Isaiah 64

1Ìwọ ìbá fa ọ̀run ya kí o sì sọ̀kalẹ̀ wá,
tí àwọn òkè ńlá yóò fi wárìrì níwájú rẹ!
2Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí iná mú ẹ̀ka igi jó
tí ó sì mú kí omi ó hó,
sọ̀kalẹ̀ wá kí orúkọ rẹ le di mí mọ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ
kí o sì jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó wárìrì níwájú rẹ!
3Nítorí nígbà tí o bá ṣe àwọn ohun ẹ̀rù tí àwa kò nírètí,
o sọ̀kalẹ̀ wá, àwọn òkè ńlá sì wárìrì níwájú rẹ̀.
4 aLáti ìgbà àtijọ́ kò sí ẹni tí ó gbọ́ rí
kò sí etí kan tí ó gbọ́ ọ,
kò sí ojú tí ó tí ì rí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn rẹ,
tí ó máa ń ṣe nǹkan lórúkọ àwọn tí ó dúró dè é.
5Ìwọ a máa wá fún ìrànlọ́wọ́ àwọn tí wọn
ń fi ayọ̀ ṣe ohun tó tọ́,
tí ó rántí ọ̀nà rẹ.
Ṣùgbọ́n nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀ sí wọn,
inú bí ọ.
Báwo ni a ó ṣe gbà wá là?
6Gbogbo wa ti dàbí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́,
gbogbo òdodo wa sì dàbí èkísà ẹlẹ́gbin;
gbogbo wa kákò bí ewé,
àti bí afẹ́fẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ wa ti gbá wa lọ kúrò.
7Ẹnikẹ́ni kò pe orúkọ rẹ
tàbí kí ó gbìyànjú láti dì ẹ́ mú;
nítorí ìwọ ti fi ojú rẹ pamọ́ fún wa
ó sì jẹ́ kí àwa ṣòfò dànù nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.

8Síbẹ̀síbẹ̀, Olúwa, ìwọ ni Baba wa.
Àwa ni amọ̀, ìwọ ni amọ̀kòkò;
gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
9Má ṣe bínú kọjá ààlà, ìwọ Olúwa:
Má ṣe rántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa títí láé.
Jọ̀wọ́, bojú wò wá, ni a gbàdúrà,
nítorí ènìyàn rẹ ni gbogbo wa.
10Àwọn ìlú mímọ́ rẹ ti di aṣálẹ̀;
Sioni pàápàá di aṣálẹ̀, Jerusalẹmu di ahoro.
11Tẹmpili mímọ́ ológo wa, níbi tí àwọn baba wa ti yìn ọ́,
ni a ti fi iná sun,
àti ohun gbogbo tí í ṣe ìṣúra wa ti dahoro.
12Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí, Olúwa, ìwọ
ó ha sì tún fi ara rẹ pamọ́ bí?
Ìwọ ó ha dákẹ́ kí o sì fìyà jẹ wá kọjá ààlà bí?
Copyright information for YorBMYO